Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Irọ to jinna soootọ ni ahesọ kan to gba ori ayelujara pe awọn agbebọn ti gbakoso awọn igbo kan nipinlẹ Kwara, ti wọn si fẹẹ maa tibẹ ṣakọlu sawọn olugbe agbegbe naa. Kọmisanna ọlọpaa, CP Tuesday Assayomo, lo sọrọ yii di mimọ ninu
atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ naa, Ọkasanmi Ajayi, fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ ta a lo tan yii. O sọ pe irọ funfun balau ni iroyin ni, ki awọn olugbe agbegbe naa ma foya, ki wọn maa gbe pẹlu ifọkanbalẹ tori pe ẹgbẹ ọdẹ ati fijilante ti n kaakiri gbogbo inu igbo to wa niluu naa lati ri i daju pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia olugbe ipinlẹ naa. O tẹsiwaju pe gbogbo awọn to n gbe iroyin ọhun kiri lori ayelujara kan fẹẹ si awọn eniyan lọna ni, ti wọn si fẹẹ da ibẹru-bojo silẹ fawọn eeyan ipinlẹ Kwara ati gbogbo Naijiria lapapọ.
O ni kọmiṣanna ọlọpaa atawọn ẹṣọ alaabo to ku ko ni i kaaarẹ ọkan lati ri i daju pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia ọmọ ilu ati olugbe ipinlẹ Kwara.
O rọ awọn olugbe ilu naa ki wọn maa ta awọn ẹṣọ alaabo lolobo nigbakuugba ti wọn ba kẹẹfin ohun to ṣe ajeji tabi ti wọn ba ri awọn afurasi layiika wọn. O fi kun un pe ki gbogbo awọn iyalọja pada sidii okoowo, ki wọn si maa ba isẹ wọn lọ lai foya.