Awọn agbebọn pa adari ẹgbẹ APC ti wọn ji gbe lasiko tawọn fijilante fẹẹ doola ẹmi rẹ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ti awọn fijilante nipinlẹ Kwara fẹẹ doola ẹmi awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn jigbe, ni wọn doju ibọn kọra wọn, ti wọn si ṣeku pa ọkan ninu awọn ti wọn ji gbe, Arabinrin Olomi Sundr, adari awọn obinrin ni wọọdu Koro, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara.

Tẹ o a ba gbagbe, Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ to kọja, ti awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn to mẹjọ pari eto ayẹyẹ ibura wọle fawọn oloye ẹgbẹ oṣelu ọhun niluu Ilọrin tan ti wọn n pada sile wọn ni awọn ajinigbe ji wọn gbe laarin Ararọmi Ọpin si Obbo Ile, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara. Eeyan marun-un mori bọ, wọn si ti gbe wọn lọ si ileewosan fun itọju to peye. Ṣugbọn obinrin ti wọn ṣeku pa yii wa lara awọn mẹta ti wọn jigbe lọ.

Awọn fijilante lo fẹ lọọ doola ẹmi awọn mẹtẹẹta lọwọ awọn ajinigbe, eyi lo fa a ti wọn fi doju ibọn kọra wọn, ti ọta ibọn si ba obinrin yii, to si ku lojiji.

Arabinrin Yẹmisi Oloke Oni, lati wọọdu Eruku sọ pe ogun miliọnu ti awọn ajinigbe naa fẹẹ gba ni wọn ti ṣeto kalẹ, ṣugbọn awọn fijilante ni dandan ni ki wọn doola ẹmi wọn lai san owo kankan.

Leave a Reply