Awọn agbebọn pa ẹṣọ Emir ipinlẹ Zamfara meji, ọlọpaa mẹta ati awakọ rẹ

Faith Adebọla, Eko

Wọn ti sinku mẹjọ lara awọn to wa pẹlu Ẹmir ilu Kaura Namoda, nipinlẹ Zamfara, Alaaji Sanusi Mohammad Asha, tawọn agbebọn pa lasiko ti wọn da wọn lọna nigba ti wọn n bọ lati ilu Abuja lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee yii, ṣugbọn ẹ ni wọn ku iku oro lojiji.

ALAROYE gbọ pe oju ọna marosẹ Abuja si Zamfara niṣẹlẹ ọhun ti waye, wọn ni ọba alaye naa n dari rele lati ibi ipade kan to lọọ ṣe nilu Abuja ni, aajin si ti jin ko too de ibi tawọn agbebọn ọhun ti lugọ de e.

Gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, NAN, ṣe sọ, ko sohun to ṣe Ẹmir Sanusi, ori ko o yọ, ṣugbọn eeyan mẹjọ lo ba iṣẹlẹ ibanujẹ naa lọ, inu ọkọ Toyota Hilux kan to kọwọọrin pẹlu ọba alaye naa ni wọn wa, lara wọn ni ẹṣọ aafin meji, ọlọpaa mẹta, dẹrẹba Ẹmir, ati awọn ijoye Zamfara meji.

Wọn ni eto ti n lọ lọwọ bayii lati lọọ ko oku awọn to doloogbe naa, ki wọn le sin wọn, bẹẹ lawọn agbofinro ti bẹrẹ si i tọpa awọn agbebọn to ṣọṣẹ ọhun.

Ọba yii ni alaga igbimọ lọbalọpa ipinlẹ Zamfara.

Leave a Reply