Awọn agbebọn pa oṣiṣẹ So-Safe sẹnu iṣẹ ni Sagamu

Gbenga Amos, Abẹokuta

Oru Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni awọn eeyan kan ti wọn ṣi n wa di ba a ṣe n sọ yii pa ọkan ninu ikọ ẹṣọ alaabo So-Safe ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Jinmi Ogunjinmi, lasiko toun atawọn ẹlẹgbẹ rẹ lọọ ṣiṣẹ idaabobo ni adugbo Areke, ni Sagamu, nipinlẹ Ogun.

Alukoro ajọ naa, Moruf Yusufu, ṣalaye pe lasiko ti oun ati ikọ ajọ naa marun-un mi-in lọọ dọdẹ awọn agbebọn kan to maa n dana ni titi nla to wa ni Rẹmọ ni awọn agbebọn kan ṣeku pa a. O ni oteẹli kan wa ni agbegbe naa ti awọn eeyan naa maa n sa pamọ si.

Moruf ni ko pẹ ti awọn eeyan naa de agbegbe yii ni wọn ri mọto Hillux funfun kan to n bọ, ni wọn ba da a duro. Ṣugbọn kaka ki mọto naa duro, niṣe lo fere si i. Eyi lo mu ki Ogunjinmi ati oṣiṣẹ So-Safe mi-in ti wọn n pe ni Kazeem Akodu Elewedu tẹle mọto naa.

Bi awọn eeyan naa ṣe ri i pe wọn ti n le awọn bọ ni wọn bẹrẹ si i yinbọn nigba ti wọn de iwaju oteẹli kan ti wọn n pe ni Walex Hotel, ni Areke, ni wọn ṣina ibọn fun ikọ fijilante yii. Ki wọn si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ibọn naa ti mu Ogunjinmi balẹ, bẹẹ ni awọn eeyan naa si sa lọ pẹlu mọto Hillux ti wọn wa ninu rẹ naa.

Ohun to ṣe ni laaanu ni pe Ogunjinmi ni iya laye, bẹẹ lo fi iyawo ati ọmọkunrin kan saye lọ.

Leave a Reply