Awọn agbebọn pa ọkan ninu awọn oloye ẹgbẹ APC n’Ifọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹgbẹ APC ipinlẹ Ondo ti kẹdun iku ọkan ninu awọn oloye ẹgbẹ ọhun, Ọnarebu Bamidele Emmanuel Isibor, ti awọn agbebọn ṣeku pa lagbegbe Imoru, Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ, lopin ọsẹ to kọja.

Atẹjade kan ti Alukoro ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, Alex Kalẹjaye, fi sita l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ṣalaye pe

asiko ti oloogbe ọhun atawọn oloṣelu kan nijọba ibilẹ Ọsẹ n pada siluu Ifọn lati Imoru ti wọn ti lọọ ṣepade lawọn agbebọn da ọkọ wọn lọna, ti wọn si ṣina ibọn fun wọn.

O ni baba ọlọmọ marun-un ọhun nikan lo fara pa ju ninu gbogbo awọn to wa ninu ọkọ lasiko ti akọlu yii waye.

Lẹyin ikọlu ọhun lo ni awọn eeyan kan sare gbe ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgọta naa lọ sile-iwosan, nibi to pada ku si lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

Kalẹjaye juwe iku Ọnarebu ọhun bii adanu nla fun ẹbi rẹ, ẹgbẹ APC nijọba ibilẹ Ọsẹ, nibi to ti jẹ akọwe wọn, ati apapọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo.

 

Leave a Reply