Awọn agbebọn pa ọlọde mẹrin, wọn tun ji ọmọ olori ilu gbe sa lọ

Adewale Adeoye

Nnkan ko fara rọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lasiko tawọn agbebọn kan ya wọnu ilu kekere kan ti wọn n pe ni Maraban Agyaro, to wa loju ọna marosẹ Birmin-Gwari Kakanhi, nipinlẹ Kaduna, ti wọn si pa awọn ọdẹ adugbo mẹrin nifọna-fọnṣu.

Yatọ sawọn ọdẹ adugbo mẹrin  ti wọn da ẹmi wọn legbodo, wọn tun kina bọ awọn ọkada bii meje, ti wọn si tun ji ọkada marun-un gbe sa lọ.

ALAROYE gbọ pe irọlẹ Tọsidee, ọhun tawọn araalu yii n bọ lati ọja ti wọn araalu ọhun maa n na lọsọọsẹ ni awọn oniṣẹ ibi naa lọọ dena de wọn. Wọn da mọto wọn duro, wọn si ji dẹrẹba mọto to n ko awọn araalu ọhun bọ sa lọ.

Alaga ẹgbẹ Birnin-Gwari Emirates Progressive Union tẹlẹ, Ishaq Usman Kasai, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn oniṣẹ ibi naa ji ọmọ olori ilu Rafin-Gora, nijọba ibilẹ yii kan naa gbe sa lọ ni nnkan bii aago mọkanla aarọ kutukutu yii kan naa.

Ṣa o, awọn ṣọja atawọn ọmọ ogun oju ofurufu ilẹ wa ti n ṣewadi nipa iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si n wa awọn oniṣẹ ibi naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, ASP Mansur Hussain, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ ọhun, awọn si maa too fọwọ ofin mu awọn ọdaran ọhun laipẹ.

Leave a Reply