Awọn agbebọn pa pasitọ, wọn tun jiyawo ẹ gbe lọ

Monisọla Saka

Ojiṣẹ Ọlọrun kan, Rẹfurẹndi Musa Mairimi, ti i ṣe alaamojuto ijọ ECWA, agbegbe Buda two, Kasuwa Magani, nijọba ibilẹ Kajuru, ipinlẹ Kaduna, ni wọn lawọn agbebọn kan ti da ẹmi ẹ legbodo bayii.

Gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kirisiti, ẹka ti ipinlẹ Kaduna, Rẹfurẹndi Joseph Hayab, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin ṣe sọ, o ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, lawọn ẹni ibi yii huwa laabi ọhun. Lẹyin ti wọn pa pasitọ ọhun tan ni wọn tun ji iyawo ẹ gbe lọ. Amọ si iyalẹnu awọn eeyan, awọn eeyan bii ọgọrun-un kan ti wọn ti ji gbe tẹlẹ kaakiri ipinlẹ ọhun ni wọn tu silẹ.

O tẹsiwaju pe awọn eeyan to to bii ọgọrun-un kan ti wọn ti wa lakata awọn agbenigbowo yii lati bii oṣu mẹfa sẹyin, agaga awọn eeyan ti wọn ji gbe lawọn ijọba ibilẹ bii Kauru, Jaba, Kachia, Kagarko ati Kajuru ti gba itusilẹ lọwọ awọn eeyan ọhun.

O ni ni kete ti wọn dibo aarẹ tan, awọn ojiṣẹ Ọlọrun mẹta lawọn ajinigbe yii gbe sa lọ, ti wọn si n beere miliọnu lọna aadọta Naira, (50,000), lọwọ awọn mọlẹbi ọkan ninu awọn pasitọ to wa lakata wọn ọhun.

O ni, “Ṣugbọn nigba to ya ni wọn din owo idunaadura wọn si miliọnu marun-un lati aadọta miliọnu Naira. Iru ipo ta a bara wa niyẹn nipinlẹ Kaduna. Ta lẹni tẹ ẹ fẹẹ sunkun si lọrun, ta lẹni teeyan fẹ lọọ sa ba, latigba tọrọ ijinigbe yii kuku ti bẹrẹ ni Kaduna, ko ti i fi bẹẹ si pe wọn n fi panpẹ ofin gbe ẹnikẹni”.

Leave a Reply