Awọn agbebọn pa Samson l’Akungba Akoko, wọn tun ji ọkada rẹ lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

 

Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ iku ọlọkada kan, Samson Owodayọ, tawọn onisẹẹbi kan pa lasiko to wa lẹnu iṣẹ oojọ rẹ niluu Akungba Akoko, lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun ọhun sọ fun iyawo rẹ, Damilọla, lọjọ naa pe oun ni awọn onibaara oun kan ti oun fẹẹ gbe lọ sibi kan pẹlu ọkada tuntun to ṣẹṣẹ ra ni nnkan bii ọsẹ diẹ sẹyin.

Oun funra rẹ ni wọn lo gbe iyawo ati ọmọ rẹ lọ si ṣọọsi lọjọ ta a n sọ yii, bi wọn ṣe n pari isin tan ni nnkan bii aago meje alẹ lo tun gbe wọn pada sile wọn to wa lagbegbe Villa, niluu Akungba, ko too dagbere fun wọn pe oun fẹẹ lọọ gbe awọn ti oun ba ṣadehun.

Kayeefi nla lo jẹ fawọn ẹbi ọlọkada naa nigba tawọn eeyan kan ransẹ si wọn pe wọn ri oku rẹ nibi ti wọn pa a si lẹgbẹẹ ileesẹ burẹdi kan ti ko fi bẹẹ jinna sile to n gbe.

Awọn agbebọn ọhun la gbọ pe wọn ji ọkada rẹ gbe sa lọ lẹyin ti wọn pa a tan, owo ati kaadi ipọwo (ATM) nikan lawọn eeyan ba ti wọn ko le e laya nibi tí wọn pa a si.

Iṣẹlẹ yii ti da ibẹru nla sọkan awọn eeyan agbegbe naa, eyi lo si ṣokunfa bí wọn ṣe n rawọ ẹbẹ sijọba atawọn ẹsọ alaabo lati gbe igbesẹ ti iru rẹ ko fi ni i waye mọ.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

O ni oun nigbagbọ pe laipẹ lọwọ yoo tẹ awọn to ṣiṣẹ ibi naa ki wọn le jiya to tọ labẹ ofin.

Leave a Reply