Awọn agbebọn ti pa mẹta ninu awọn akẹkọọ fasiti ti wọn ji gbe ni Kaduna

Mẹta ninu awọn akẹkọọ Yunifasiti Greenfield to wa niluu Kaduna, ni awọn agbebọn to ji wọn gbe ti pa bayii.

Abule kan nitosi ọgba ileewe giga naa ni wọn ju oku awọn akẹkọọ naa si. Ibẹ ni wọn ti ri wọn lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.

Kọmiṣanna feto aabo ati ọrọ abẹle nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan, ṣalaye pe abule kan ti wọn n pe ni Kwanana Bature, ti ko jinna si ọgba yunifasiti naa, ni wọn ti ri oku awọn akẹkọọ naa.

Alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn ya wọ inu ọgba ileewe ọhun, to wa ni Kasarami, nijọba ibilẹ Chikun, nipinlẹ Kaduna, ti wọn si ji awọn akẹkọọ mọkanlelogun ko. Bi awọn agbebọn naa ṣe ko wọn ni wọn ni miliọnu lọna ẹgbẹrin (800m) naira lawọn yoo gba kawọn too le tu wọn silẹ.

Ẹnu eleyii ni wọn wa ti wọn fi ba oku mẹta ninu awọn akẹkọọ naa ni abule kan ti ko jinna rara si ileewe ọhun.

Kọmiṣanna naa ni awọn ikọ alaabo kan ti waa ko oku awọn akẹkọọ yii lọ si mọṣuari.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ti bu ẹnu atẹ lu pipa ti wọn pa awọn akẹkọọ yii. O ni iwa ika ati alailaaanu loju buruku ni wọn hu.

Gomina naa waa rọ gbogbo awọn araalu lati fọwọsowọpọ lati le awọn afẹmiṣofo ti wọn fẹẹ ba orileede Naijiria jẹ yii danu.

Bakan naa lo ba gbogbo mọlẹbi awọn akẹkọọ ti wọn pade iku ojiji yii kẹdun.

O fi kun un pe ohun ko ni i jẹ ki eti araalu di si bi gbogbo ẹ ba ṣe n lọ.

Leave a Reply