Awọn agbebọn ti tun ji Ẹmia ilẹ Hausa gbe wọ’gbo o

Faith Adebọla

Lati nnkan bii aago mẹsan-aabọ alẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii lawọn janduku agbebọn ti yi ibusun ati itẹ Dokita Mahmud Ahmed Aliyu, Ẹmia ilu Wawa Gbere, ni agbegbe Borgu, nipinlẹ Niger pada, dipo ori itẹ, inu igbo lọba naa wa bayii, akata awọn agbebọn ti wọn ji i gbe lo wa di ba a ṣe n sọ yii.

Ba a ṣe gbọ, niṣe lawọn agbebọn ti iye wọn pọ ya bo tinu tode aafin ọba ilẹ Hausa yii lalẹ ọjọ tiṣẹlẹ yii waye, niṣe ni ibẹrubojo da bo awọn eeyan nigba ti wọn n gburoo ibọn ni kọṣẹkọṣẹ, tawọn agbebọn naa si n wọnu gbogbo yara o wa laafin Ẹmia ọhun.

Wọn ni kabiyesi ọhun ti wa ninu iyẹwu pẹlu awọn iyawo ati ọmọ rẹ, taara tawọn agbebọn naa si wọ iyẹwu naa, niṣoju awọn mọlẹbi rẹ ọhun ni wọn fi gan ọba naa lapa, wọn si mu un lọ sori ọkan lara awọn ọkada ti wọn gbe wa, o di inu igbo.

Wọn ni wọn o yinbọn pa ẹnikẹni, bẹẹ ni wọn o lu Aliyu tabi ṣe e leṣe.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, DSP Wasiu Abiọdun ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O sọ fun Ajọ akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe loootọ niṣẹlẹ naa waye ati pe titi di ba a ṣe n sọ yii, awọn o ti i gbọ ipe latọdọ awọn agbebọn ti wọn sọ Ẹmia ilu dero inu igbo yii, bẹẹ lawọn o ti i mọ pato ibi ti wọn wa, ṣugbọn eto ti n lọ, iṣẹ iwadii naa ko si duro, lati doola ẹmi Ẹmia Wawa kuro lọwọ awọn afẹmiṣofo ajinigbe yii.

“Gbogbo awọn ti wọn ṣiṣẹ yii la n gbe igbesẹ lati mu, ki wọn si jiya labẹ ofin, a si fẹẹ fọgbọn ṣe e ki wọn ma lọọ wu kabiyesi lewu,” gẹgẹ bi Abiọdun ṣe wi.

Leave a Reply