Awọn agbebọn ti wọn ji ọba alaye gbe ni Kogi n beere miliọnu lọna ọgbọn naira

Faith Adebọla

Taati miliọnu, iyẹn miliọnu lọna ọgbọn naira (#30m) lawọn janduku ajinigbe to ji ọba onipo-ki-in-ni kan, Adogu tilu Eganyi, Alaaji Mohammed Adembe, gbe sọ pe awọn maa gba ki ori-ade naa too le kuro lakata awọn, ko si gbatẹgun ominira lẹẹkan si i.

Nnkan bii aago kan ọsan Ọjọruu, Wẹsidee yii, lawọn ajinigbe naa kan sawọn mọlẹbi Kabiyesi naa lori aago lati sọ nnkan ti wọn maa mu wa bi wọn ba fẹ ki ọba naa dẹni ominira, wọn ni taati miliọni ni ki wọn fi sọwọ sawọn ni werewere.

Irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lawọn janduku naa gbọna ẹburu yọ si Ọba Adembe lọna marosẹ Okene si Adogo, nigba to n pada saafin rẹ.

Wọn l’Ọba Adembe nikan lo wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, funra rẹ lo wakọ, nigba tiṣẹlẹ buruku naa waye, o n bọ lati ode kan ni, o si ti de itosi ilu rẹ ki wọn too yọ si i, wọn bẹrẹ si i yinbọn, ni wọn ba da mọto naa duro, wọn wọ ọba alaye naa bọọlẹ ninu ọkọ, ti wọn si wọ ọ wọgbo lọ.

Latigba naa nileeṣẹ ọlọpaa atawọn eeyan ilu Eganyi, nijọba ibilẹ Ajaokuta, ti ko si hilahilo bi wọn ṣe maa ri ọba alaye naa gba pada.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, Ọgbẹni Williams Ayah, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ pe loootọ lo waye, ṣugbọn o lawọn agbofinro kan ti n ṣiṣẹ kara lati tọpasẹ awọn kọlọransi ẹda naa, o lawọn n fọgbọn ṣe e ni ki wọn ma lọọ da ẹmi ọba legbodo.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ mẹta ṣaaju iṣẹlẹ yii lawọn agbebọn ji ọga agba ileeṣẹ apoogun Azeco Pharmaceuticals Company, Ọgbẹni AbdulAzeez Ọbajimọ, lagbegbe Okene, nipinlẹ Kogi.

Ninu iṣẹlẹ ọjọ naa lawọn ajinigbe naa ti yinbọn pa ọkunrin kan, Habeeb Anda, atawọn meji mi-in.

Titi di ba a ṣe n sọ yii, ọga agba naa ṣi wa lakata awọn ajinigbe ọhun.

Leave a Reply