Miliọnu mẹwaa lawọn agbebọn to ji odidi idile kan gbe l’Ajọwa Akoko fẹẹ gba

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn agbebọn to ji tọkọ-taya kan atawọn ọmọ wọn mẹta gbe lagbegbe Ajọwa Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, ti ni miliọnu mẹwaa naira lawọn fẹẹ gba lọwọ awọn ẹbi wọn ki awọn too fi wọn silẹ.

Ọgbẹni Ibrahim Olusa, iyawo rẹ, atawọn ọmọ wọn la gbọ pe wọn ji gbe laarin oju ọna marosẹ Ajọwa ati Ayẹrẹ, nipinlẹ Kogi, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Opin ọsẹ to kọja yii ni wọn lọkunrin ọhun ko awọn ẹbi rẹ lẹyin lati ilu Abuja ti wọn n gbe, ki wọn le waa ba wọn sọdun Ajinde ni Daja Ajọwa, to jẹ ilu abinibi rẹ.

Aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti wọn n pada si ibugbe wọn lawọn ajinigbe ọhun da wọn lọna nibi kan ti ọna ti bajẹ, ti wọn si fipa ko gbogbo wọn wọnu igbo lọ.

Awọn ajinigbe ọhun la gbọ pe wọn ti kan sawọn ẹbi Olusa to wa l’Ajọwa Akoko, ti wọn si ni wọn gbọdọ san miliọnu mẹwaa naira ti wọn ba si fẹẹ ri awọn maraarun-un pada laaye.

Leave a Reply