Awọn agbebọn to ji Rẹfurẹndi gbe l’Akurẹ n beere fun ogun miliọnu

[social_warfare buttons=”facebook”]

 

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Iranṣẹ Ọlọrun to n ṣiṣẹ pẹlu sọọsi Katoliiki lagbegbe Akurẹ, Rẹfurẹndi Fada Joseph Ajayi, lawọn agbebọn kan ti ji gbe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.
Ẹni-ọwọ Ajayi to jẹ alufa ijọ Peteru Mimọ to wa niluu Ilara-Mọkin, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, ni wọn da ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla rẹ lọna laarin Ikẹrẹ-Ekiti si Iju, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lasiko to n pada si ibugbe rẹ.
Iṣẹlẹ yii ni ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Ẹniọwọ Victor Ibiyẹmi to jẹ akọwe agba fun olori ijọ Katoliiki nipinlẹ Ondo, Bisọọbu Jude Arogundade.
Ẹniọwọ Ibiyẹmi ni awọn ajinigbe ọhun ti kan si awọn alasẹ ijọ Katoliiki lati waa san ogun miliọnu Naira fun itusilẹ ojisẹ Ọlọrun ti wọn ji gbe naa.
Gbogbo akitiyan wa lati ri Abilekọ Funmi Ọdunlami to jẹ alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ba sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun lo ja si pabo, ṣe ni nọmba foonu rẹ kọ ti ko wọle titi ta a fi ko iroyin yii jọ tan.

Leave a Reply