Awọn agbebọn to wa ninu igbo lagbegbe Ariwa/Iwọ-Oorun ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un lọ-Gumi

Faith Adebọla

Ilu-mọ-ọn-ka aṣaaju ẹsin Musulumi l’Oke-Ọya nni, Sheik Abubakar Gumi, ti sọ pe ọna kan toun mọ tijọba le gba fopin si iwa ọdaran awọn janduku agbebọn ni ki wọn fa wọn loju mọra, ki wọn jọ jokoo sọrọ, ki wọn si fun wọn lohun ti wọn ba beere fun, aijẹ bẹẹ, ijinigbe, akọlu sawọn ileewe ati itajẹsilẹ to n waye nilẹ wa ko ni i lọ bọrọ.

Ọkunrin naa tun fi kun un pe awọn janduku agbebọn toun mọ, ti wọn wa lawọn igbo to wa yika agbegbe Ariwa/Iwọ-Oorun Naijiria nikan ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un lọ, ka ma ti i sọ nipa awọn agbegbe mi-in ti wọn ti lugọ si kaakiri orileede yii.

Gumi sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu iweeroyin Punch, lori ọrọ awọn akẹkọọ ileewe Tegina Islamic School, tawọn agbebọn kan ji gbe loṣu to kọja nipinlẹ Niger, ti wọn si n beere miliọnu lọna igba naira (#200 million) gẹgẹ bii owo tawọn maa gba lọwọ awọn obi ọmọ naa lati tu wọn silẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ti din owo naa ku si miliọnu aadọjọ naira (#150,000).

Gumi ni: “A ti n ba awọn agbebọn yii sọrọ, pe ki wọn ṣaanu awọn ọmọleewe ti ko mọwọ mẹsẹ yii, a o tiẹ mọ ipo tawọn ọmọ naa wa bayii.

Iṣẹlẹ yii ti jẹ kawọn eeyan mọ pe awọn agbebọn yii ko fi tọrọ ẹsin tabi ẹya ṣe, ko seyii to kan wọn nipa ẹsin, owo ni wọn n wa ni tiwọn. Ka ma gbagbe pe wọn o kawe, ko ṣeni to ran wọn nileewe tijọba tabi ti aladaani. Maaluu ni wọn n da kiri laye wọn, igba ti wọn si waa ja ọgbọn towo gọbọi le fi wọle yii, wọn ba kuku tẹra mọ ọn.

Ṣugbọn tijọba ba pe wọn jokoo, ti wọn ba wọn sọrọ, ti wọn fa wọn loju mọra pẹlu eto ẹkọ ati awọn nnkan mi-in bii ipese iṣẹ gidi fun wọn, wọn maa fi iṣẹ ti wọn n ṣe yii silẹ. Awọn kan lara wọn taa ti ba sọrọ ti jawọ ninu iwa ijinigbe, afi awọn kan ti wọn tun pada sẹnu ẹ nigba tijọba o ri tiwọn ro.

Ọkunrin naa ni ijọba ipinlẹ Niger ti n ṣapa lati gba awọn ọmọ yii pada, ṣugbọn owo o fi bẹẹ si lapo ijọba ipinlẹ ọhun ni.

O ni ko sọna tijọba yoo fi daabo bo awọn akẹkọọ lawọn ileewe wa ayafi ti wọn ba kọkọ fopin si iwa ijinigbe ati awọn janduku agbebọn, aijẹ bẹẹ, ko si ileewe to le mori bọ.”

O fikun un pe “ki lo de tijọba o le ba wọn sọrọ. Wọn o pọ, eeyan le ka wọn leni eji, niṣe ni kijọba ba wọn sọrọ. Ni agbegbe Ariwa/Ila-Oorun nikan, boya ni wọn maa ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un lọ, ṣugbọn bintin niyẹn jẹ laarin awọn ti wọn wa kaakiri orileede yii o. Bijọba ṣe n kọ lu wọn lati oju ofurufu yii n ba ọrọ jẹ si i ni, tori nigba ti ẹ ba n pa ọmọ ọlọmọ, ẹ ma gbagbe pawọn ọmọ tiwa naa wa lakata wọn o.”

Leave a Reply