Faith Adebọla
O kere tan, oku eeyan mẹtadinlogun lawọn agbofinro atawọn ọlọdẹ ti ri ṣa jọ lasiko ti ikọ agbebọn kan ṣakọlu si abule Mundung-Mushu ati Kopnanle, nijọba ibilẹ Bokkos, nipinlẹ Plateau, loru mọju ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ ọmọ ibilẹ agbegbe ọhun, Bokkos Cultural Development Council, (BCDC), fi lede lori iṣẹlẹ ibanujẹ yii, wọn ni oru mọju, ni nnkan bii aago kan ku iṣẹju mẹẹẹdogun, nigba tawọn eeyan ti sun oorun asunwọra, lawọn afurasi agbebọn naa ya bo awọn abule mejeeji yii, ti wọn si bẹrẹ si i dọdẹ araalu bii ẹni dọdẹ okete.
Niṣe lawọn apaayan naa n tina bọle, bawọn araalu si ṣe n taji, ti kaluku n sa asala fẹmii rẹ ninu eefin ati ina to n jo bulabula, bẹẹ lawọn agbebọn naa n yinbọn mọ wọn, ti wọn si n pa wọn bii eṣinṣin.
Eeyan mẹsan-an ni wọn yinbọn pa labule Mandung-Mushu, nigba ti wọn pa mẹjọ labule Kopnanle.
Wọn ni fun bii wakati meji lawọn afẹmiṣofo naa fi n ṣe bo ṣe wu wọn, ti ko si sẹni to too bẹẹ lati da wọn lọwọ kọ, lai fi ti ibudo awọn ṣọja to wa ni sẹkiteriati ijọba ibilẹ Bokkos, ti ko fi bẹẹ jinnu sawọn abule yii pe.
Gomina ipinlẹ Plateau, Caleb Mutfwang, ti fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ buruku yii. Ninu atẹjade kan ti Oludari eto iroyin rẹ, Ọgbẹni Gyang Bere, buwọ lu lorukọ gomina, o kẹdun pẹlu awọn to fara gba ninu iwa odoro yii, o si ṣeleri pe gbogbo awọn amookunṣika naa lawọn maa ṣawari wọn lati le da sẹria to tọ fun wọn labẹ ofin.