Awọn agbebọn tun gboro ni Jos, wọn paayan mẹwaa, wọn dana sun’le rẹpẹtẹ

Faith Adebọla

 Bi oku ṣe sun rẹpẹtẹ ni abule Te’egbe, nijọba ibilẹ Bassa, nipinlẹ Plateau, bẹẹ leefin gba gbogbo oju ọrun latari bawọn agbebọn ṣe ya bo agbegbe ọhun laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, ti wọn paayan mẹwaa, o kere tan, wọn si dana sun ọpọlọpọ ile.

Ba a ṣe gbọ, ọpọlọpọ awọn araalu ti Ọlọrun ko yọ lo fara gbọgbẹ yannayanna lasiko ti wọn n sa lọ, wọn ni bi wọn ṣe n sa wọ’gbo lawọn agbebọn naa n dana ibọn ya wọn.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn ọdọ agbegbe naa ti wọn pe ni Miango Youth Development Association, Ọgbẹni Nuhu Bitrus, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, NAN, pe awọn ọlọpaa atawọn fijilante ti n wa awọn araalu to sọnu sinu igbo lasiko akọlu naa, bakan naa ni wọn ti n tọpasẹ awọn janduku agbebọn naa, lati fofin mu wọn.

O leeyan mẹwaa lawọn ṣi ri oku wọn, awọn si ti ko awọn ti wọn ṣeṣe lọ sọsibitu fun itọju.

“Ọjọ ọfọ ni oru mọju yii tun jẹ fawa eeyan Rigwe o, nipinlẹ Plateau, awọn agbebọn ti paayan rẹpẹtẹ ni Te’egbe, wọn ti sọ ibẹ dahoro o, wọn paayan tan, wọn tun dana sun’le pẹlu gbogbo dukia wọn ni, ẹ gba wa o.

Oku mẹwaa la ṣi ri ka, wọn ti n wa awọn to ku kaakiri inu igbo, a si ti ko awọn oku naa lọ si mọṣuari, eeyan mẹta la ṣi ri ti ọta ibọn ba, wọn ti n gba itọju lọwọ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Ubah Ọgaba, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ọga ileeṣẹ aabo ti n forikori lati gbe igbesẹ gidi lori ẹ.

Leave a Reply