Awọn agbebọn tun ji awọn oyinbo mẹta gbe l’Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn oyinbo mẹta to n mojuto atunṣe ọna Ikaram si Akunnu Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, lawọn agbebọn kan ti ji gbe sa lọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ yii waye lẹyin tawọn oyinbo agbaṣẹṣe ọhun ti ṣiwọ iṣẹ ọjọ naa ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ.

Awọn ọlọdẹ ibilẹ, fijilante atawọn ọlọpaa agbegbe Akoko la gbọ pe wọn ti wa ninu igbo to wa lagbegbe naa lati ṣawari awọn ti wọn ji gbe ọhun lọnakọna.

Ko ti i ju bii ọjọ mẹta sẹyin ti wọn ji awọn ero inu ambulansi kan gbe laarin Ajọwa Akoko si Iyere, nipinlẹ Kogi, ti wọn ko si ti i mọ ibi tawọn eeyan ọhun wọlẹ si titi di ba a ṣe n sọrọ yii.

Akala ti Ikaram, Ọba Andrew Mọmọdu, ti rọ ijọba lati ko ọpọlọpọ ẹsọ alaabo wa si agbegbe naa kọwọ le tete tẹ awọn onisẹẹbi ọhun ki wọn too ṣe awọn to wa ni igbekun wọn leṣe. Adele ọga agba ọlọpaa to n mojuto ẹkun Ikarẹ Akoko, Ọgbẹni Timibra Toikima, rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹsọ alaabo, ki wọn si tete waa fẹjọ ẹnikẹni ti wọn ba fura si sun ni teṣan.

Leave a Reply