Awọn agbebọn tun ji ọmọleewe mẹẹẹdogun ko ni Zamfara, wọn yinbọn pa ọlọpaa ati ọlọdẹ meji to n ṣọ wọn

Faith Adebọla

Ojumọ ire kọ lo mọ fọpọ awọn obi ati mọlẹbi awọn akẹkọọ kọlẹẹji ẹkọ imọ ọgbin ati ẹranko, College of Agriculture and Animal Science, to wa nijọba ibilẹ Bakura, nipinlẹ Zamfara. Awọn janduku agbebọn ti lọọ ji awọn akẹkọọ ileewe naa ati tiṣa wọn gbe loru mọju ọjọ Aje, Mọnde yii, eeyan mẹtadinlogun ni wọn ni wọn ji gbe, bo tilẹ jẹ pe meji lara wọn pada jajabọ, nigba ti wọn raaye sa mọ wọn lọwọ.

Ohun ta a gbọ ni pe nnkan bii aago mọkanla aabọ ọganjọ oru ọjọ Aiku, Sannde, lawọn agbebọn naa ya bo ọgba ileewe ọhun, ọkada rẹpẹtẹ ni wọn gun wa, bi wọn si ṣe debẹ ni wọn ṣina ibọn bolẹ.

Wọn ni oju ẹsẹ ni wọn ti yinbọn pa ọlọpaa kan to n ṣọ awọn ọmọleewe naa, wọn si gbe ibọn rẹ lọ. Bakan naa ni wọn tun yinbọn pa baba ọlọdẹ meji ti wọn wa pẹlu ọlọpaa naa, ibi tawọn ọlọdẹ naa fara pamọ si ni wọn ti yinbọn fun wọn.

Lẹyin eyi ni wọn ji awọn ọmọleewe ọhun, tọkunrin tobinrin wọn, ninu awọn yara gbalasa ti wọn n sun, ni wọn ba ko gbogbo wọn lọ, ati awọn tiṣa wọn to wa nibugbe tijọba kọ fun wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara, SP Mohammed Shehu, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ni oootọ niṣẹlẹ ọhun waye, awọn si ti n ṣewadii lori ẹ, ati pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa ati awọn ologun ti wọle ipade lati gbe igbesẹ to yẹ.

Ṣugbọn ninu ọrọ kan ti Igbekeji Ọga agba ileewe ọhun, Ọgbẹni Ali Atiku, ba awọn oniroyin sọ lọsan-an ọjọ Aje, o ni meji lara awọn ti wọn ji gbe naa ti jajabọ, niṣe ni wọn sa mọ wọn lọwọ loru nigba ti wọn n ko wọn lọ.

Awọn meji ọhun, tiṣa kan ati ọmọleewe kan ni wọn fori jagbo pada saarin ilu, wọn si ti mu wọn lọ fun itọju iṣegun.

Eyi kọ ni igba akọkọ ti awọn afẹmiṣofo maa ṣakọlu sileewe yii. Loṣu to kọja, awọn janduku naa ji Ọga agba ileewe naa, Ọgbẹni Habibu Mainasara, gbe, wọn si beere fun miliọnu marun-un lọwọ awọn mọlẹbi ẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn dunaa duraa lẹyin eyi.

Ọjọ kẹta ni wọn tu baba naa silẹ lẹyin ti wọn ti gba owo gẹgẹ bii adehun.

Tẹ o ba gbagbe, aarin ọsẹ to kọja yii lawọn agbebọn ṣeku pa kansẹlọ tẹlẹ kan, Alaaji Tukur Hassan, ninu ile rẹ to wa lagbegbe Sabon Gida, nijọba ibilẹ Bungudu, ipinlẹ Zamfara yii kan naa.

Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ l’Ọjọbọ, ọsẹ to kọja pe nnkan bii aago mejila ọsan ni wọn de ile Oloogbe Hassan, o jọ pe wọn ti n tẹle e tẹlẹ, o ni wọn sọ pe koloogbe naa ko ẹyin rẹ sawọn, wọn si yinbọn fun un latẹyin, wọn pa a fin-in-fin-in.

Hassan ni kansẹlọ to figba kan ṣoju Wọọdu Sankalawa-Sabon, niluu Bungudu.

Iṣẹlẹ ti Hassan yii waye lọjọ keji tawọn agbebọn naa ji iyawo kansẹlọ mi-in to n tọmọ lọwọ kan, Abilekọ Hassana Maudaki, toun pẹlu ọmọ-ọwọ rẹ, ọmọ oṣu mẹjọ, ni wọn ji gbe, bo tilẹ jẹ pe wọn pada tu wọn silẹ lọjọ keji, lẹyin ti wọn ti gbowo.

Ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn lobinrin naa, ile wọn to wa ninu ọgba ile ijọba, Government Reserved Quarters, laduugbo Damba, ni Zamfara.

Leave a Reply