Monisọla Saka
Ojiṣẹ Ọlọrun ijọ Katoliiki meji kan, Ẹni ọwọ Donatus Cleophas Sulaiman ati Ẹni ọwọ John Mark Chietnum, ni wọn ti tun ji gbe niluu Kaduna, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karundinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022.
Ninu atẹjade ti adari eto iroyin ijọ Katoliiki ipinlẹ Sokoto Fada Chris Omotosho, gbe jade lo ti ṣalaye pe ijinigbe ọhun waye ni Christ the King Catholic Church, to wa ni Yalding Garu, ijọba ibilẹ Lee, nipinlẹ Kaduna, ni deede aago marun-un irọlẹ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun.
Ọmọtosho ni Sulaiman ni adari ijọ St. Joseph’s Catholic Church, to wa laduugbo Shagari Low-cost, nipinlẹ Katsina, labẹ akoso ijọ Katoliiki Kafanchan, lagbegbe Sokoto.
“A rọ awọn eeyan Ọlọrun pata lati fi ọkan mimọ kun wa lọwọ ninu adura fun wọn lati pada silẹ pẹlu alaafia ati ayọ, ati lati tete da wọn silẹ laaye”.