Awọn agbebọn tun ya wọ ileewe kan ni Kaduna, wọn ko ọpọlọpọ akẹkọọ lọ

Ni nnkan bii aago kan oru ni awọn janduku agbebọn kan tun ya wọ ileewe girama kan ti wọn n pe ni Bethel Secondary School, nijọba ibilẹ Chikun, nipinlẹ Kaduna, ti wọn si ko ọpọlọpọ awọn akẹkọọ ti ko sẹni to ti i le sọ iye wọn lọ.

A gbọ pe ṣe ni wọn ya wọ inu ọgba ileewe naa, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn leralera lati dẹruba awọn akẹkọọ naa. Lasiko tawọn ọmọleewe naa sa jade lati sa asala fun ẹmi wọn ni awọn janduku yii bẹrẹ si i ko wọn, ko si ti i sẹni to mọ iye ti wọn jẹ di ba a ṣe n sọ yii.  

Leave a Reply