Awọn agbebọn tun ya wọ Kagara, wọn paayan mẹrin, wọn ji imaamu atawọn mẹẹẹdọgbọn mi-in gbe sa lọ

Faith Adebọla

 

 

 

Egbinrin ọtẹ lọrọ awọn bawọn agbebọn ṣe n ṣọṣẹ nipinlẹ Niger da bayii, bi wọn ṣe n pana ọkan ni omi-in n ru jade, bawọn eeyan ṣe n dupẹ pe awọn akẹkọọ mejidinlọgbọn ri itusilẹ gba Kagara, bẹẹ lawọn agbebọn tun gbinaya lagbegbe Kagara yii kan naa, nipinlẹ Niger, wọn yinbọn pa eeyan mẹrin, wọn ji awọn mẹẹẹdọgbọn gbe sa lọ.

Iṣẹlẹ yii la gbọ po waye lọwọ ọsan ọjọ Abamẹta, Satide yii, ni awọn adugbo mẹrin kan, Madaka, Karaku, Sambuga ati Yakila, agbegbe Kagara ti wọn ti ji awọn ọmọleewe yii kan naa ni.

Obinrin meje la gbọ pe o wa lara awọn mẹẹẹdọgbọn ti wọn ko wọgbo, wọn ni meji ninu awọn obinrin naa gbe ọmọ ikoko dani, wọn laipẹ yii ni wọn bimọ, bẹẹ ni Imaamu abulẹ Rubo wa lara wọn.

Yatọ si tawọn eeyan ti wọn pa ni Karuku, atawọn ti wọn ji gbe, wọn lawọn afurasi ọdaran afẹmiṣofo ọhun tun ko awọn maaluu sa lọ.

Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) lawọn ṣọja atawọn ọlọpaa ti n tọpasẹ awọn apamọlẹkun ẹda ọhun.

Leave a Reply