Awọn agbebọn ya bo abule meji l’Ọṣun, wọn ji Fulani mẹta gbe 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn agbebọn ti wọn to mẹjọ la gbọ pe wọn ti kọ lu abule meji to jẹ ti awọn Fulani darandaran nitosi ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, ti wọn si ji eeyan mẹta gbe.

Awọn abule naa ni Idi Araba ati Laagi Fulani loju ọna Iwo/Aáwẹ́/Ọyọ. Nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ Furaidee ọsẹ to kọja lawọn agbebọn ọhun ya wọbẹ.

Awọn ti wọn ji gbe naa ni Ojonla Adams, ẹni ọdun mejidinlogoji to jẹ Fulani, Hamzat Ibrahim ati Deere Ibrahim ti wọn jẹ ẹya Bororo.

Alaroye gbọ pe ede Fulfude lawọn agbebọn naa n sọ nigba ti wọn debẹ, wọn si beere lọwọ awọn ara abule pe ta lo lowo ju laarin wọn, ẹni naa ni wọn si kọkọ gbe, ki wọn too ko awọn meji yooku.

Tesan ọlọpaa to wa niluu Iwo, ni wọn ti kọkọ lọọ fi ọrọ naa to wọn leti, kia lawọn ọlọpaa, awọn ọlọdẹ atawọn aṣọgbo ya bo agbegbe naa, ti wọn si ti bẹrẹ si i wa wọn lati aarọ ọjọ Satide to kọja.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ẹnikan to n jẹ Hamidu Ibraheem to n gbe lagbegbe Testing Ground, niluu Iwo, lo lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti.

Hamidu ṣalaye pe awọn agbebọn naa ji ọmọ oun, Ojonla Adams atawọn meji mi-in gbe, latigba naa si lawọn ẹṣọ alaabo ti bẹrẹ si i wa wọn.

Ọpalọla ni iṣẹ ti n lọ lọwọ lati ṣawari awọn ti wọn ji gbe naa.

Leave a Reply