Awọn agbebọn ya wọ abule kan ni Kwara, wọn fipa ba obinrin meji lo pọ, wọn ṣa awọn kan ladaa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lawọn agbebọn afurasi Fulani darandaran ti ko si ẹni to da wọn mọ ya wọ abule kan ti wọn n pe ni Nuku, nijọba ibilẹ Kaima, nipinlẹ Kwara, wọn ṣa eeyan meji niṣakuṣaa, bẹẹ ni wọn ji awọn ọmọbinrin meji gbe lọ. Lẹyin ti wọn fipa ba wọn lo pọ tan ni wọn tu wọn silẹ.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, fi lede niluu Ilọrin, ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lo ti sọ pe owurọ kutu Wẹsidee ni iṣẹlẹ naa waye, nigba ti awọn agbebọn ọhun ya wọ ile Alaaji Hassan Yunusa, niluu Nuku, nijọba ibilẹ Kaima, wọn tu gbogbo ile wọn, wọn n wa owo, ṣugbọn wọn ko ri owo kankan, ni wọn ba ṣa Alaaji Yunusa ati Woru Yunusa, ni iṣakuṣaa, wọn si ji awọn ọmọbinrin meji gbe lọ nibẹ, ṣugbọn nigba ti wọn fipa ba awọn ọmọ naa lo pọ tan ni wọn tu awọn mejeeji silẹ.

Ni bayii awọn mejeeji ti wọn ṣa ladaa ti n gba itọju nileewosan ijọba to wa ni ilu Woro, ti awọn dokita si ti n ṣe oniruuru ayẹwo fawọn obinrin ti wọn fipa ba lo pọ.

Afọlabi ni iwadii ti n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa, awọn ẹṣọ alaabo yoo si ri i daju pe ọwọ tẹ awọn ọdaran naa.

Leave a Reply