Awọn agbebọn tẹnikan ko mọ ti ya wọnu abule Gangarbi, to wa nijọba ibilẹ Rano, nipinlẹ Kano, nibẹ ni wọn ti ji ọkunrin ẹni ọgọta ọdun kan gbe, ti wọn si tun yin awọn eeyan meji kan nibọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ naa, Manman Dauda fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ. O ṣalaye pe ni nnkan bii aago kan aabọ oru ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, niṣẹlẹ naa waye.
O ni, “Ni nnkan bii aago kan aabọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni awọn ọlọpaa gba ipe pajawiri kan pe awọn agbebọn lọọ kogun ja wọn labule Gangarbi, nijọba ibilẹ Rano, nipinlẹ Kano, nibẹ ni wọn ti ji ọkunrin ti wọn n pe ni Alaaji Na’ayya Gangarbi, gbe lọ sibi tẹnikan o mọ.
Apapọ ikọ awọn ọlọpaa teṣan naa, ikọ JTF atawọn ikọ ti wọn n gbogun ti ijinigbe, ni wọn pa laṣẹ lati sare lọ sibudo iṣẹlẹ naa”.
Dauda ni wọn yin awọn eeyan meji nibọn, ẹsẹ ọtun ni wọn ti yinbọn fun Masumuru Ukaisha, nigba ti wọn yin Salisu Ibrahim nibọn nibi ejika ẹ lapa osi. Awọn mejeeji yii ni wọn ti gbe digbadigba lọ sileewosan ijọba Rogo, General Hospital.
O tẹsiwaju pe awọn ti ko ọpọlọpọ awọn ẹṣọ alaabo, to fi mọ awọn fijilante adugbo, pẹlu nnkan ija oloro lọ si agbegbe naa, lati le tọpasẹ awọn agbebọn yii, ki wọn si fi panpẹ ofin gbe awọn atawọn janduku mi-in ti wọn n da omi alaafia agbegbe ibẹ ru.
Dauda ṣalaye siwaju si i pe iwadii ti bẹrẹ, lojuna ati mu awọn ajinigbe naa, ki wọn si doola ẹmi awọn ti wọn ji gbe lọ.