Awọn agbebọn yii laya o, ilu abinibi gomina Zamfara ni wọn ti lọọ ji ọmọleewe rẹpẹtẹ gbe lọsan-an gangan

Faith Adebọla

Kaka ki ewe agbọn dẹ, koko lo n le si i lọrọ awọn janduku agbebọn to n ṣoro bii agbọn lapa Oke-Ọya ile wa bayii, aya ti ko wọn debii pe wọn o foru boju ṣiṣẹẹbi wọn mọ, ọsan gangan ni wọn tun lọọ ji awọn ọmọọlewe rẹpẹtẹ ko niluu Kaya, ti i ṣe ilu abinibi gomina ipinlẹ Zamfara.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago mejila kọja iṣẹju diẹ lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee yii, lawọn agbebọn ti wọn pọ rẹpẹtẹ gun ọkada wọ ilu Kaya, taara ni wọn fori le ileewe girama ijọba, Government Day Secondary School, to wa nijọba ibilẹ Maradun, nipinlẹ Zamfara, wọn nileewe naa ko jinna si agboole ti wọn bi Gomina Bello Matawale si, to ti ṣe kekere rẹ. Wọn yinbọn ni koṣẹ-koṣẹ, lawọn aladuugbo ba bẹrẹ si i sa asala fẹmii wọn, bẹẹ lawọn agbebọn naa bẹrẹ si i ko awọn ọmọọlewe ti wọn n kawe lọwọ ni kilaasi wọn sori awọn ọkada ti wọn gbe wa, wọn si ko eyi to pọ ju lọ lara wọn wọgbo lọ.

Oṣiṣẹ ọfiisi gomina ọhun ti ko fẹẹ sọ orukọ ara rẹ fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni ko ti i sẹni to mọ iye awọn ọmọleewe tawọn agbebọn naa ji gbe wọgbo, ṣugbọn Gomina Matawale ti gbọ si iṣẹlẹ yii.

“Loootọ niṣẹlẹ yii waye, o baayan ninu jẹ pe titi tawọn agbebọn naa fi pari iṣẹ buruku wọn, ko sẹni to le yẹ wọn lọwọ wo.

Gomina ati awọn lọgaalọgaa lẹka eto aabo ti n ṣepade lori ọrọ yii, ireti wa pe wọn yoo fi atẹjade lede lori rẹ laipẹ, wọn yoo si sapa lati doola ẹmi awọn majeṣin ọhun,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply