Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọpọ awọn eeyan ilu Ajọwa Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, ni wọn ko le pa ibanujẹ wọn mọra, niṣe lawọn mi-in si sunkun kikoro nigba ti wọn gbe oku awakọ kan, Toyin Mala, wọ ilu ọhun lọjọ Aiku, Sannde ọsẹ ta a wa ninu rẹ yii.
Mala to ni ọkọ akero to fi n na Ajọwa si Abuja lo pade iku ojiji lagbegbe Akunnu Akoko, lati ọwọ awọn ajinigbe lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ko si iṣoro tabi idiwọ kankan fun ọkunrin awakọ ọhun lati ilu Abuja to ti gbera titi to fi de ibi kan ti wọn n pe ni Agọ Jinadu, lagbegbe Akunnu Akoko, nibi tawọn ajinigbe kan ti yọ si i lojiji.
Bo ṣe kofiri awọn agbebọn naa ni wọn lo duro lojiji, to si ki ọkọ rẹ bọ rifaasi, to si tun n gbiyanju ati yi ori ọkọ naa pada ko le maa sa lọ.
Ko ti i raaye ṣe eyi tan tawọn janduku ọhun fi da ibọn bo o, wọn pa a loju-ẹsẹ ti wọn si ji awọn ero inu ọkọ rẹ gbe sa wọnu igbo lọ.
Awọn meji pere ti wọn raaye sa asala fun ẹmi wọn ni wọn waa royin ohun to sẹlẹ fawọn eeyan nile.
Iṣẹlẹ yii lo mu ki adele ọba Akunnu Akoko, Ọmọọba Tọlani Orogun, maa parọwa si ijọba lati gbe igbesẹ lori ati gba awọn eeyan Akoko silẹ lọwọ akọlu gbogbo igba lati ọwọ awọn Fulani ajinigbe.
Ọmọọba Orogun ni ọrọ awọn janduku agbegbe naa ti fẹẹ maa kọja ohun tawọn araalu le fara da mọ, nitori pe agbẹ meji ni wọn kun bii ẹran Ileya lasiko ti wọn lọọ ka wọn mọ inu oko wọn ni Ikakumọ Akoko.
Ọpọ awọn agbẹ lo ni wọn ti sa lọna oko wọn nitori akọlu awọn Fulani, eyi to n ṣokunfa ọwọngogo ounjẹ lagbegbe naa lọwọlọwọ.
Adele ọhun ni ohun to le din akọlu igba gbogbo naa ku ni ki ijọba ṣeto ati ko ọpọ awọn ẹsọ alaabo wa si agbegbe Akunnu.
Ọga ọlọpaa teṣan Oke-Agbe, Paulinus Onnah, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni loju-ẹsẹ lawọn ti debẹ, ti awọn si gbe oku awakọ naa lọ si mọṣuari.