Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko ti i mọ ibi ti wọn ti wa ti yinbọn pa oluṣoagutan ijọ Aguda kan torukọ ẹ n jẹ Luke Adeleke, l’Ogunmakin, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun.
Ẹni-ọwọ Luke Adeleke tawọn eeyan mọ si Fada Luke, ẹni ọdun mejidinlogoji (38), n ti ibi isin kan bọ lalẹ ọjọ Keresimesi ku ọla ni gẹgẹ ba a ṣe gbọ, lasiko naa lawọn agbebọnrin ti wọn ti n ṣọ ọ tẹlẹ si da a lọna, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn fun un titi ti ọkunrin naa fi dagbere faye.
Bakan naa lawọn kan sọ pe lasiko to n lọ sibi isin ijọ Aguda to jẹ ti ori ijọ mi-in l’Ogunmakin ni wọn yinbọn pa a.
Ori ijọ ti wọn n pe ni ‘Gotta Parish’ to wa nipinlẹ Ogun ni wọn ti gbe Fada Adeleke kuro, ti wọn si gbe e wa sibi to n dari bayii, nipinlẹ Ogun kan naa, kawọn kan too da ẹmi ẹ legbodo lọjọ ọdun Keresimesi ku ọla.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
O ni ọjọ Ẹti naa lagbara, nitori awọn kan n yinbọn lagbegbe Ogunmakin, to jẹ awọn agbebọn naa kọju ija sawọn ọlọpaa, tawọn agbofinro naa n da a pada fun wọn lakọlakọ ni.
Alukoro sọ pe pẹlu ọta ibọn lawọn kan sa lọ ninu awọn agbebọn naa.