O ma ṣe o, awọn agbebọn yinbọn pa ọba alaye l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe ni ibanujẹ dori agba awọn eeyan ijọba ibilẹ Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ, kodo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a wa yii, pẹlu bawọn agbebọn kan ṣe yinbọn pa kabiesi ilu ọhun, Ọba Israel Adeusi, to jẹ Onifọn tilu Ifọn.

Ọba alaye ọhun ni wọn lo rin si asiko tawọn ajinigbe naa n ṣiṣẹ ibi wọn lọwọ lagbegbe Ẹlẹgbẹka, nitosi Ifọn, nigba to n bọ lati ibi ipade awọn lọbalọba ti wọn ṣe l’Akurẹ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee.

Ohun ta a kọkọ gbọ ni pe loju ẹsẹ tawọn agbebọn naa ri ọkọ Onifọn to yọ ni wọn ti da ibọn bolẹ, wọn lawọn eeyan kan sare gbe kabiesi ọhun lọ si ileewosan ijọba to wa niluu Ọwọ ni kete ti won ṣakiyesi pe baba ti fara gbọta, nibẹ lawọn dokita si ti fidi rẹ mulẹ fawọn to gbe e lọ pe ọba ti waja.

Ninu iroyin mi-in ta a gbọ, wọn lawọn ajinigbe ọhun ti ji kabiesi gbe tẹlẹ, asiko tawọn ẹsọ alaabo kan n gbiyanju ati lepa wọn ki wọn le gba a silẹ lọwọ wọn ni wọn ri oku rẹ nibi ti wọn gbe e ju si.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ọpọlọpọ awọn agbofinro lawọn ti ko lọ si agbegbe naa ki wọn le ṣawari awọn oniṣẹẹbi ọhun nibikibi ti wọn ba farapamọ si.

Leave a Reply