Awọn agbebọn yinbọn pa olori awọn Fulani ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Owurọ Ọjọruu, Wẹsidee, lawọn agbebọn ya bo agbegbe Lamba, nijọba ibilẹ Aṣa, nipinlẹ Kwara ti wọn si ṣeku pa Seriki n Fulani ipinlẹ Kwara, Alhaji Abdullahi Guruku, ti ọpọ eniyan mọ si Alhaji Mallam.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila oru ni awọn agbebọn naa ya bo ilu Lamba, ti wọn si n pariwo, ‘Astagifirullahi, lailah ilanllahu’, ti wọn si n rọjo ibọn ko too di pe wọn wọ yara lọọ ba a, ti wọn si yinbọn pa a.

A gbọ ni pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn ṣẹṣẹ fi i jẹ oye Seriki ni ilu Lamba, lẹyin ti wọn pa a tan, wọn tun gbe ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ati awọn foonu rẹ lọ.

Awọn olugbe agbegbe naa ti a fọrọ wa lẹnu wo sọ pe lẹyin ti wọn pa oloogbe tan, wọn tun tọ ojule kọọkan lọ, ti wọn si n pariwo pe awọn ki i ṣe ṣọja, ojulowo Boko Haram ni awọn, bakan naa ni wọn n sọ pe ọmọkunrin to ba to bẹẹ ko jade sita, ti wọn si fi ibọn da gbogbo ilu ru, odidi wakati meji gbako ni wọn sọ pe awọn agbebọn ọhun fi yinbọn, ti ko si si ẹni to to to bẹẹ ko jade si wọn.

 

Wọn ti sin oloogbe naa lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee,  ni ilana ẹṣin Musulumi ti gbogbo ilu Lamba si kan gogo bayii.

Leave a Reply