Taofeeq Surdiq, Ado-Ekiti
Ọpọlọpọ awọn agunbanirọ ni wọn farapa yannayanna lasiko ti ile ti wọn n gbe to wa ni ni Ìsẹ̀/Ọ̀rún-Ekiti, nijọba ibilẹ Emure, nipinlẹ Ekiti wo lulẹ.
Awọn agunbanirọ naa ti ọpọlọpọ wọn jẹ obinrin ni wọn fara pa, ti wọn si ti ko wọn lọ si ileewosan to wa ni ibudo wọn fun itọju.
Gẹgẹ bi awọn t’ọrọ naa ṣoju wọn ṣe ṣalaye fun ALAROYE, ile ọhun ti wọn lo ti pẹ, nitori latigba ti wọn ti da ipinlẹ Ekiti silẹ lo ti wa nibẹ lo sadeede wo ni nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ naa, lakooko ti awọn to n sin ijọba naa n sun lọwọ.
Oṣiṣẹ ajọ naa kan to ba ALAROYE sọrọ sọ pe loootọ ni ile awọn obinrin to wa ninu Ibudo awọn agunbanirọ sadeede da wo ni kutukutu owurọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu yii.
‘’A dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko si ẹni to ku sinu iṣẹlẹ naa, awa oṣiṣẹ ti a wa ninu ibudo naa la sare waa yọ awọn diẹ ti ile naa wo lu, ti a si ko wọn lọ si ileewosan fun itọju to peye’.
Awọn agunbanirọ naa ti wọn to bii ẹgbẹrun kan ati aabọ (1,500) ni wọn wa ni ipagọ naa fun idanilẹkọ ọlọsẹ mẹta ki iṣẹlẹ ile wiwo naa too sẹlẹ.
ALAROYE gbọ pe awọn meji pere ni wọn fara pa.