Awọn ajagun-gbalẹ kọlu ọba tuntun l’Ekoo, wọn fẹẹ ji i gbe lọ

Iyalenu nla lo ṣi n jẹ nigba tawọn janduku ajagungbalẹ kan ya wọ aafin Ọba Olukayọde Raji niluu Isiu n’Ikorodu l’Ekoo lanaa, ti wọn si fẹẹ ji kabiyesi to ṣẹṣẹ dori ipo naa gbe sa lọ.

Wọn ni bi wọn ṣe n yinbọn, bẹẹ ni wọn n fi ohun ija oloro mi-in ṣe awọn eeyan leṣe, ti kaluku si bẹrẹ si sa asala fun ẹmi rẹ.

A gbọ pe o le ni ọgọta eeyan to farapa yannayanna, ti ibọn si ba ọkan lara awọn ọmọ kabiyesi yii.

Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹjọ ọdun yii ni Kọmiṣanna fun akanṣe iṣẹ l’Ekoo, Ogbeni Wale Ahmed, gbe ọpa aṣẹ fun Ọba Olukayọde Raji gẹgẹ bi ọba tuntun fun ilu Isiu. Ohun to wa n ya ọpọ eeyan lẹnu ni pe, ki lo le mu awọn janduku fẹẹ ji ọba tuntun ọhun gbe lọ.

Ọba Olukayọde ninu ọrọ ẹ ṣalaye pe, “Ṣadeede la ri awọn janduku ọhun ti wọn ya wọ aafin pẹlu oriṣiriṣii ohun ija lọwọ, bi wọn ṣe n yinbọn, bẹẹ ni wọn ba dukia olowo iyebiye jẹ. Emi gan-an ni wọn fẹ ji gbe o, ṣugbọn ori lo ko mi yọ nitori loju-ẹsẹ tawọn fijilante eleto aabo ilu ti gbọ lawọn naa ti kora wọn jọ, ti wọn si kọlu awọn eeyan ọhun gidigidi.”

Lara awọn ohun ti wọn bajẹ ni mọto ọba tuntun yii, bẹẹ lawọn to wa ki kabiyesi ku ayọ oye tuntun naa fara gbọgbẹ pẹlu, tawọn kan si ti wa ni ọsibitu bayii nibi ti wọn ti n gba itọju.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbọ si iṣẹlẹ naa, bẹẹ lawọn ọlọpaa ti wa ninu ilu naa, ti ọwọ si ti tẹ awọn afurasi mẹta ti wọn sọ pe o ṣee ṣe ki wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ buruku yii.

 

Leave a Reply