Awọn ajagungbalẹ ya wọ inu ọgba Guru Maharaj Ji n’Ibadan, wọn ṣe eeyan meji leṣe

Ọlawale Ajao, Ibadan
O kere tan, meji ninu awọn ọmọ ijọ One Love Family, iyẹn ijọ Satguru Maharaj Ji, lo fara pa yanna-yanna nigba ti awọn ajagungbalẹya ya bo abule Guru Maraji to wa loju ọna Eko s’Ibadan lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Akọwe iroyin Satguru Maharaj Ji, Ọgbẹni Ojo Mogbadewa, lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Iṣẹ lawọn eeyan wa n ṣe lọwọ ninu oko ta a da si ori ilẹ yẹn, ti awọn janduku to le lọgọrun-un niye fi ya de pẹlu katakata ti wọn gbe wa lati fi bo ilẹ yẹn. Nibi ti awọn eeyan wa ti n gbiyanju lati da wọn duro pe ki ni wọn n wa Iori ilẹ Maharaj Ji, ni wọn ti ya lu wọn, ti wọn si lu wọn bii ẹni lu bara.
‘‘Meji ninu awọn eeyan wa ni wọn fara pa yanna-yanna. Titi di ba a ṣe n sọrọ yii ni wọn ṣi n gba itọju lọwọ.
Ẹẹmeji ọtọọtọ la ti gba idalare nile-ẹjọ lori ilẹ yii, ti ile-ẹjọ ti fidi ẹ mulẹ pe awa la ni i, a si rọ awọn alaṣẹ lati tẹ ẹ waa gbe igbesẹ to maa fidi ẹ mulẹ pe awa la ni ilẹ yii, a ko lo ilẹ onilẹ. A ti pinnu lati wa nnkan ṣe si ori ilẹ yii ko ma baa kan wa bẹẹ lasan mọ, afi bi awọn ajagungbalẹ yẹn ṣe lọọ ka awọn eeyan wa mọbẹ lọjọ Mọnde.

“Orukọ diẹ ninu awọn janduku yẹn ni “Ọmọọba Dare Adelẹyẹ, Ismaila Adeleke, Ayo Akinade, Wasiu Atẹrẹ, Rasheed Karimu, Ismaila Ige, Mutairu Ige, Taofeek Ọlagoke ati eyi kan bayii ti wọn n pe orukọ inagijẹ rẹ ni Ladọja.”

Leave a Reply