Awọn ajinigbe fi ọga ṣọja ti wọn ji gbe l’Ekiti silẹ

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn ajinigbe ti fi ajagun-fẹyinti nni, Jide Ijadare, silẹ lẹyin ọjọ mẹta to ti wa nigbekun wọn.

Ọsan ọjọ Iṣegun, Tusidee, to kọja, ni wọn gbe ọkunrin naa ati oṣiṣẹ kan nileeṣẹ rẹ ti wọn ti n ṣe epo pupa, eyi to da silẹ soju ọna Ijan-Ekiti si Isẹ-Ekiti.

Bi wọn ṣe ya bo ibudo naa ni wọn yinbọn pa ọkunrin kọngila kan ki wọn too gbe ajagun-fẹyinti to ṣiṣẹ nileeṣẹ ologun ilẹ Amẹrika tẹlẹ naa ati ẹlomi-in.

Nigba to di ọjọ keji ni wọn beere fun miliọnu lọna ogun naira.

Ṣugbọn ni nnkan bii aago mẹrin kọja iṣẹju mẹẹẹdogun irọle yii ni wọn fi awọn eeyan naa silẹ, a si gbọ pe mọlẹbi Ijadare sanwo ti wọn beere fun.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sannde Abutu, sọ pe loootọ ni Ijadare ti gba ominira, ṣugbọn oun ko mọ boya wọn sanwo kankan fun itusilẹ ẹ.

Abutu ni awọn gbagbọ pe iṣẹ tawọn ṣe pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ lo jẹ kawọn eeyan ọhun kuro lakata awọn ajinigbe.

Leave a Reply