Awọn ajinigbe gbe iyawo ọga-agba ileeṣẹ ijọba Ekiti tẹlẹ

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn agbebọn kan ti ji iyawo olori ileeṣẹ ijọba tẹlẹ kan, Abilekọ Funmilayọ Ọṣalusi, gbe nile ẹ to wa loju ọna Poli ijọba apapọ, niluu Ado-Ekiti.

Obinrin naa ni iyawo wọnlẹwọnlẹ-agba (Surveyor General) tẹlẹ l’Ekiti, Ọgbeni Felix Ọladapọ Ọṣalusi, ẹni to dagbere faye lọdun to kọja.

Abilekọ Ọṣalusi to jẹ oṣiṣẹ kansu ijọba ibilẹ Ado la gbọ pe awọn agbebọn ọhun tan jade ninu ile ẹ ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ, ti wọn si gbe e lọ pẹlu mọto.

Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, ṣalaye pe ile obinrin naa lawọn agbebọn mẹta ọhun ti ṣe bii ẹni pe wọn fẹẹ ri i, bo si ṣe jade si geeti lati mọ awọn to n wa a ni wọn rọra mu un wọ mọto wọn, ti wọn si gbe e lọ.

O ni Kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti, Tunde Mobayọ, ti ko awọn ọtẹlẹmuyẹ si gbogbo agbegbe iṣẹlẹ naa ati ayika ibi ti wọn gbe obinrin ọhun gba, bẹẹ lawọn ọlọpaa yoo ṣiṣẹ pẹlu ikọ Amọtẹkun, fijilante atawọn ọdẹ lati ri obinrin naa gba pada lalaafia.

 

Leave a Reply