Awọn ajinigbe ji Alaaji Ismail Lawal gbe n’Ibadan

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Inu ibanuje nla lawọn mọlẹbi baba agba kan, Alhaji Ismail Lawal tawọn eeyan mọ si ‘Lọwọ Ori’ wa bayii pẹlu bawọn ajinigbe ṣe ji i gbe ni nnkan bii aago mejila oru Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu kọkanla yii, lawọn kan ti wọn fura si gẹgẹ bii ajinigbe deede ya bo ile Alaaji  ‘Lowo Ori’, to wa lagbegbe Labi, ni Moniya, niluu Ibadan. Awọn ajinigbe naa wọ aṣọ ọlọpaa, ti awọn kan si wọ aṣọ ṣọja laarin wọn.

Gẹgẹ bi aladuugbo kan to ni ka fi orukọ bo oun laṣiiri ṣe ṣalaye fun akọroyin wa, o ni awọn eeyan naa pọ, mọto Hilux bii mẹrin ni wọn gbe wa.

O ni awọn dukia baba naa ni wọn kọkọ ko ko too di pe wọn gbe baba naa lọ pẹlu mọto Hilux ti wọn gbe wa si ile baba naa.

Wọn ti fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa ẹka ti Mọniya, niluu Ibadan, leti.

Leave a Reply