Awọn ajinigbe ji arinrin-ajo mẹjọ to n lọ s’Ilọrin lati Kano, wọn tun mu ẹni to lọọ fun wọn lowo silẹ  

Stephen Ajagbe, Ilorin

Awọn arinrinajo mẹjọ kan to n bọ wa siluu Ilọrin lati Kano tawọn ajinigbe ji gbe lati ọjọ kejila, oṣu kọkanla, ọdun yii, ṣi wa lahaamọ awọn to ji wọn gbe.

Ọkan lara mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe naa to ni ka forukọ boun laṣiri ṣalaye pe ọna Zaria si Kano lawọn ajinigbe naa ti kọ lu ọkọ tawọn eeyan naa wọ, wọn yinbọn fun awọn mẹrin ninu ọkọ ko too di pe wọn ko awọn mẹjọ lọ.

Onitọhun ni awọn ajinigbe naa pe awọn, wọn si beere fun miliọnu mẹwaa naira gẹgẹ bii owo iyọlọfin, awọn si gbọdọ san owo naa laarin wakati mejidinlaaadọta, pẹlu ikilọ pe bawọn ba sọ fun awọn agbofinro, wọn maa pa awọn eeyan naa.

O ni ọna Oko Olowo, niluu Ilọrin, lawọn ajinigbe naa kọkọ ni kawọn gbe owo naa lọ, nibi ti ẹni to maa gba a ti maa pade awọn, ṣugbọn ṣadeede ni wọn tun yi i pada, ti wọn ki i ṣe ibẹ mọ.

“Lẹyin ta a dunaa-dura, wọn din owo naa ku si miliọnu mẹta naira, a si gba lati gbe owo naa lọ sibikan lọna Zaria si Kano, loju ọna marosẹ Kaduna.

O ni si iyalẹnu awọn, awọn ajinigbe naa mu ọkunrin tawọn ran lati gbe owo naa lọ sọdọ, wọn ni miliọnu kan aabọ naira lo gbe wa dipo miliọnu mẹta naira tawọn jọ ṣe adehun. Wọn ni owo ounjẹ lasan lowo ti onitọhun gbe wa.

Wọn waa rawọ ẹbẹ sawọn agbofinro lati doola awọn eeyan wọn to ti wa lahaamọ awọn ajinigbe naa lati ọjọ kejila, oṣu kọkanla.

Leave a Reply