Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Lẹyin ọsẹ meji ti wọn ji tọkọ-tiyawo kan gbe ni Ilasa-Ekiti, awọn ajinigbe ti tun ji eeyan mẹrin mi-in gbe niluu naa to wa nijọba ibilẹ Ariwa Ekiti, nipinlẹ Ekiti.
Gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ, niṣe ni awọn ajinigbe naa ya wọ inu oko kan ti wọn n pe ni Eti-Oro, ni deede aago kan aabọ oru Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn kikan kikan.
Lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn ti n yinbọn yii ni wọn ji eeyan mẹrin gbe, ti mẹta lara wọn jẹ Igbira, ti ọkan yooku si jẹ ọmọ Yoruba, to jẹ ọmọ ọdun mẹwaa. Awọn eeyan naa ni wọn ti gbe lọ si ibi ti ẹnikẹni ko ti i mọ bayii.
ALAROYE gbọ pe ariwo ibọn ti awọn ajinigbe ọhun n yin lakọlakọ lo ji gbogbo awọn to wa ni oko naa, ti onikaluku si bẹrẹ si i sa kijokijo kiri.
“Bi wọn ṣe n yinbọn soke lawọn ajinigbe naa bẹrẹ si i ya ojule kọọkan to wa ni abule naa, ti wọn si mu ọmọ ọdun mẹwaa kan ati awọn Igbira mẹta.
“Wọn ti ko wọn lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ, wọn ko si ti i kan si mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe naa.’ Bẹẹ ni ọkunrin kan to ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa ṣe ṣalaye.’
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe eeyan meji pere ni awọn ajinigbe naa ji gbe, awọn ọlọpaa si ti gba ẹni kan silẹ lara wọn.
O ni awọn agbofinro ti wa ninu igbo to wa ni gbogbo agbegbe naa, eyi to jẹ ki wọn ri ẹni kan mu ninu awọn ajinigbe naa.