Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Awọn ajinigbe kan ti ji Oloye pataki kan, Emmanuel Ọbafẹmi, gbe n’Ijan-Ekiti, nijọba ibilẹ Ayekire, nipinlẹ Ekiti.
Ọkunrin to jẹ oye Idọlọfin yii ni igbakeji ọba niluu naa, bẹẹ lo tun jẹ oniṣowo kan pataki.
Iyawo oloye yii tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni nnkan bii agogo marun-un aabọ irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, nigba ti awọn ajinigbe naa ti ko din ni mẹwaa deede ya wọ inu oko oloye yii to wa niwaju ile iwe Girama Ayọ Daramọla, loju ọna to lọ lati ilu Ijan si Ado-Ekiti.
Ọkunrin oloye yii nio nṣe iṣẹ lọwọ ninu oko rẹ ni ọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, nigba tawọn ajinigbe yii sadeede ya wọ inu oko naa, ti wọn si bẹrẹ si i yinibọn soke ki wọn too ji i gbe lọ.
Awọn agbebọn naa ni wọn sọ pe wọn ko gbe ọkọ tabi ọkada wa si inu oko naa, ṣugbọn bi wọn ṣe di oloye yii lọwọ mu ni wọn fa a wọ inu igbo kan to wa lẹgbẹẹ oko naa.
ALAROYE gbọ pe awọn ajinigbe yii ko ti i kan si awọn mọlẹbi rẹ latirọlẹ ọjọ ti wọn ti i ji i gbe.
Bakan naa ni ko si ẹnikẹni to pe wọn lori ẹrọ ilewọ lati igba naa.
Ṣugbọn awọn ọdẹ ibilẹ to wa niluu naa ti bẹ sinu igbo to wa lagbegbe naa, ti wọn si n gbiyanju lati gba ọkunrin naa silẹ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn awọn ọlọpaa atawọn ọdẹ ibilẹ ti wa ninu igbo to wa ni agbegbe naa.
Bakan naa ni ọga awọn Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, sọ pe oun ti ko awọn ẹṣọ oun lọ si gbogbo igbo to wa lagbegbe naa.
O ṣeleri pe oun ati awọn ọlọpaa ti n sa gbogbo ipa awọn lori iṣẹlẹ naa, o ṣeleri pe awọn yoo ri i oloye naa gba silẹ lai fara pa.