Awọn ajinigbe ji ọmọ China, wọn tun pa ọlọpaa kan l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn agbebọn kan ti ji ọmọ ilẹ China gbe nipinlẹ Ekiti, bẹẹ ni wọn tun pa ọlọpaa kan, wọn si tun yinbọn lu ẹlomi-in lọjọ Ẹti, Furaidee.

Ọkunrin ti wọn ji gbe ọhun la gbọ pe o jẹ ẹnjinnia, o si wa lara awọn to n ṣiṣẹ oju ọna Ado-Ekiti si Iyin-Ekiti tuntun, eyi tijọba Ekiti bẹrẹ lọdun to kọja.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ lẹnu ASP Sunday Abutu to jẹ Alukoro ọlọpaa Ekiti, ni nnkan bii aago mẹrin aabọ irọle ọjọ Ẹti lawọn agbebọn ọhun ya bo awọn eeyan naa, nigba ti wọn si pa itu ọwọ wọn ni wọn gbe ọkunrin oyinbo ọhun lọ.

Abutu ni wọn pa ọlọpaa kan, ṣugbọn ko sẹni to le fidi ẹ mulẹ boya ẹni keji tibọn ba ku tabi o ye.

O waa ni awọn ọlọpaa ti n wa awọn ajinigbe naa kaakiri awọn igbo agbegbe ọhun, igbiyanju si ti n lọ lati gba ẹni ti wọn ji gbe pada lalaafia.

Leave a Reply