Awọn ajinigbe mẹta gba idajọ iku l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Adajọ Ile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ ti ni ki wọn lọọ yẹgi fawọn ọdaran mẹta kan lori ẹsun jiji awọn sisita ijọ Katoliiki meji ati awakọ wọn gbe loju ọna marosẹ Ọrẹ s’Ekoo ni nnkan bii ọdun meji sẹyin.

Awọn ọdaran ọhun, Reuben Akinbẹhinjẹ, John Imọlẹayọ ati Ṣeun Isẹoluwa Akintan atawọn mẹrin mi-in ni wọn fẹsun kan pe wọn ji awọn eeyan ọhun gbe nibi ti ọkọ ayọkẹlẹ wọn bajẹ si ni nnkan bii aago meje alẹ.

Wọn ni odidi ọjọ mọkanla ni wọn fi de awọn ẹni ẹlẹni mọlẹ ninu igbo lẹyin ti wọn ti gba owo, foonu ati kaadi ipọwo ti wọn ba lọwọ wọn.

Bakan naa ni wọn fẹsun kan wọn pe wọn gba owo to to miliọnu kan naira lọwọ ẹbi awọn ti wọn ji gbe ọhun ki wọn too fi wọn silẹ.

Agbẹjọro ijọba, Amofin Babatunde Falọdun, ni gbogbo ẹsun mẹjẹẹjọ ti wọn fi kan awọn olujẹjọ naa lo lagbara, to si ni ijiya nla labẹ ofin orileede yii.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, Onidaajọ Ademọla Adegoroye ni ẹri ti olupẹjọ fi siwaju ile-ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe awọn mẹtẹẹta jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

O waa pasẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun wọn titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn. Bẹẹ lo ni ki iyawo afurasi ọdaran akọkọ, Abilekọ Abimbọla Akinbẹhinjẹ, lọọ san ẹgbẹrun lọna aadọta Naira gẹgẹ bii owo itanran fun ipa to ko lori iṣẹlẹ ọhun.

Meji ninu awọn olujẹjọ, Ṣeun Lajuwomi ati Lateef Fayẹmi, nile-ẹjọ ẹjọ ni ki wọn maa lọ ní alaafia niwọn bi ko ṣe si ẹri to lati da wọn lẹbi.

Leave a Reply