Awọn ajinigbe n beere fun ọgọrun-un miliọnu naira lori awọn ọl̀ọpaa mẹfa ti wọn ji ko

Jide Alabi

Titi di asiko yii lawọn ọlọpaa mẹfa kan ṣi wa lọwọ awọn ajinigbe ti wọn ko si lọwọ nigba ti wọn n lọ si ipinlẹ Zamfara lati ipinlẹ Borno.

ALAROYE gbọ pe mejọ lawọn ọlọpaa ọhun, ṣugbọn meji raaye sa mọ awọn ajinigbe ọhun lọwọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, nigba ti wọn kọ lu wọn.

Ni bayii, ninu idaamu lawọn mọlẹbi awọn ọlọpaa ọhun wa, ti wọn n wa owo ti wọn yoo fi gba awọn eeyan wọn kalẹ lọwọ awọn ajinigbe naa.

Ẁọn ni, lojuẹsẹ ti wọn ti ji awọn agbofinro yii gbe ni wọn ti kede pe ọgọrun-un miliọnu naira lawọn fẹẹ gba, ṣugbọn ohun ti a gbọ ni pe bii miliọnu mẹta-mẹta naira lawọn ẹbi kọọkan n wa kiri bayii lati fi gba awọn eeyan wọn kalẹ.

Siwaju si i, a gbọ pe ki wọn too ji wọn ko yii ni ọkan lara awọn ọlọpaa ọhun ti sọ pe oun ko ni i le ba wọn lọ, oun yoo waa pade wọn lọhun-un ni toun ni, bi wọn ti ṣe n mura lati lọ si Zamfara, nitori odidi ọjọ kan ni wọn yoo fi rin irin ọhun si Maiduguri.

Bi ọlọpaa mẹjọ ṣe ko sinu mọto niyẹn, nigba ti wọn si de Kano, niṣe ni onimọto sọ pe oun ko lọ si Zamfara mọ, mọto oun ti bajẹ.

Ninu mọto mi-in ti wọn wọ yẹn ni awọn ajinigbe ti kọ lu wọn, ti meji si raaye sa mọ wọn lọwọ, nigba ti mẹfa wa ni akolo wọn di ba a ṣe n sọ yii.

A gbọ pe niṣe ni wọn yinbọn fun ọkan ninu awọn meji to raaye sa yii lẹsẹ, ti awọn ara abule to ribi sa si si ṣeto bi wọn ṣe gbe e lọ si teṣan ọlọpaa, tawọn yẹn si gbe e lọ si ọsibitu.

Frank Mba to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpa ko ti i sọ ohunkohun lori ọrọ yii, bẹẹ lawọn to sun mọ awọn eeyan ti wọn ji gbe yii ṣi n sọ pe ọgọrun-un miliọnu naira lawọn eeyan naa n beere fun, iyẹn ti wọn ba si fẹẹ foju kan awọn ọlọpaa ọhun ti wọn ji gbe.

Leave a Reply