Awọn ajinigbe n beere ogun miliọnu lori ọba alaye ti wọn ji gbe l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Awọn ajinigbe to ji Ọba Benjamin Adeniran Ọshọ gbe l’Ekiti ti n beere ogun miliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ ọba alaye naa.

Tẹ o ba gbagbe, irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, ni awọn ajinigbe kan ji ọba alaye yii gbe nigba to n bọ lati oko rẹ to wa loju ọna Ẹda-Ile. Niṣe ni wọn da oun ati olori rẹ ti wọn jọ n bọ lọna.

A gbọ pe niṣe ni kabiyesi dọbalẹ, to n bẹ awọn ajinigbe naa pe ki wọn fi iyawo oun silẹ ko le lọọ sọ fawọn eeyan awọn nile.

Awọn ajinigbe naa yọnda olori, ṣugbọn wọn kilọ fun un pe ko gbọdọ sọ ohun to ṣẹlẹ si kabiyesi to ba dele, wọn ni afi to ba di aarọ ọjọ keji ni kobinrin naa too sọ. Ni wọn ba gbe Ọba Benjamin Adeniran Ọshọ lọ.

Ẹni kan niluu Ẹda-Ile Ekiti to sun mọ idile kabiyesi yii to ni ka forukọ bo oun laṣiiri, ṣalaye pe awọn ajinigbe ọhun fi foonu ọba naa pe mọlẹbi ẹ lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, iyẹn ọjọ keji ti wọn ji i gbe, wọn si n beere ogun miliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ.

O lawọn ẹbi da wọn lohun pe owo naa pọ, awọn ko le ri i san, nitori kabiyesi ki i ṣe olowo, awọn ẹbi rẹ naa ko si ki i ṣe ọlọrọ rẹpẹtẹ.

O ni niṣe lawọn ajinigbe pa foonu nigba tohun tawọn ẹbi sọ ko tẹ wọn lọrun, latigba naa ni wọn ko si ti pe mọ gẹgẹ bo ṣe wi.

Ọkunrin yii sọ pe awọn ẹbi tun pe foonu naa pada ki wọn le tun jọ tun ọrọ naa sọ, o ni awọn ajinigbe ti pa foonu ọhun, wọn ko si ti i fi ẹrọ ibanisọrọ mi-in pe latigba yẹn, eyi ti ko jẹ ki idunaa-dura naa ṣee ṣe mọ laarin awọn eeyan kabiyesi atawọn ajinigbe naa.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ọga awọn ẹṣọ Amọtẹkun l’Ekiti, Birigedia Joe Kọmọlafẹ, ṣalaye pe oun ko gbọ nipa idunaa-dura kankan ti wọn sọ pe o waye laarin ẹbi kabiyesi atawọn ajinigbe.

Kọmọlafẹ sọ pe awọn ọmọ ogun Amọtẹkun atawọn ẹṣọ alaabo mi-in ti wa ninu igbo tawọn ajinigbe ọhun maa n ko awọn ti wọn ba ji gbe pamọ si.  O lawọn yoo gba ọba alaye yii jade pẹlu ayọ ati alaafia laipẹ.

Leave a Reply