Awọn ajinigbe pa Serifat Adisa sitosi ileepo rẹ n’Igboọra

Dada Ajikanje

Ọpọ awọn ara ipinlẹ Ọyọ ni wọn ti n kọminu lori ọwọ ti ijọba ipinlẹ naa fi mu eto aabo. Eyi ko ṣẹyin bi awọn ajibigbe ṣe gba agbegbe naa kan, ti wọn n ji awọn eeyan gbe, ti wọn si tun n fi iku buruku pa awọn mi-in.

Eyi to tun ṣẹlẹ ni ọjọ keji ọdun tuntun, iyẹn ọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, kọ awọn ara ipinlẹ Ọyọ, paapaa ju lọ awọn eeyan Ibarapa, Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ lominu, o si da ijaya nla silẹ. Obinrin gbajumọ oniṣowo kan torukọ rẹ n jẹ Alaaja Sẹrifa Adisa to jẹ oludari ileepo kan ti wọn n pe ni ‘Subawa filling station’, to wa ni oju ọna Igboọra si Idere, ni Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, ni awọn ajinigbe pa, ti ibọn wọn si tun ba awọn ọmọkunrin meji to lọọ ra epo nileepo naa.

Ọjọ keji ọdun tuntun yii la gbọ pe awọn ajinigbe lọọ ka obinrin naa mọ ileepo rẹ naa ni nnkan bii aago mẹsan-an ku iṣẹju mẹẹẹdọgbọn alẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii. Niṣe ni wọn da ibọn bolẹ gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ lati fi deruba awọn eeyan to wa nileepo yii. Bẹẹ ni wọn si n gbiyanju lati ji obinrin to ni ileepo yii gbe, ṣugbọn ti iyẹn ko fẹẹ gba fun wọn. Eyi lo mu ki wọn fi tipa wọ obinrin naa kuro nileepo yii, ti wọn si wọ ọ lọ sinu igbo kan ti ko jinna si ileepo naa.

Asiko ti wọn n wọ obinrin yii lọ ni wọn da ibọn bolẹ lati fi deruba awọn to wa nitosi, to fi mọ awọn to wa nileepo ọhun. Ibọn naa lo lọọ ba awọn ọkunrin meji ti wọn wa lori ọkada ti wọn fẹẹ ra epo ninu ileepo naa, ti wọn si ku loju ẹsẹ ba a ṣe gbọ.

O jọ pe ibinu bi obinrin yii ṣe kọ lati tẹle awọn ajinigbe yii lo mu ki wọn yinbọn pa a sinu igbo ti wọn wọ ọ lọ.

Ẹṣọ Amọtẹkun ati awọn fijilante ni wọn pada ri oku obinrin naa ninu igbo ti wọn pa a si.

ALAROYE gbọ pe ọwọ ti tẹ marun-un ninu awọn to ṣiṣẹ ibi naa. Ọkan ninu wọn ni wọn kọkọ mu ni otẹẹli kan ti wọn n pe ni De Link, to wa ni Idere, bẹẹ lọwọ ti tun tẹ awọn mẹrin mi-in.

Wọn ti fa awọn ti wọn mu yii le ileeṣẹ ọlọpaa to n mojuto iwa ọdaran ti wọn n pe ni Operation Burst, ẹka ti agbegbe Ibarapa lọwọ.

Ọpọ awọn ti wọn mọ obinrin oniṣowo yii ni wọn royin rẹ daadaa, bẹẹ ni awọn to jẹ ọre rẹ ti n kọ ọrọ oriṣiiriṣii sori ẹrọ ayelujara nipa obinrin naa ati bi awọn ọdaju eeyan ṣe da ẹmi rẹ legbodo.

Obinrin kan to pe ara rẹ ni Rashidat Temitọpe Aderibigbe kọ ọ sori ikanni  ayelujara pe, ‘‘…iku ọrẹ mi, Alaaja Sẹrifat Adisa, ẹni ti wọn ji gbe nileepo rẹ, ti wọn si pa a ni Igboọra, Ki Ọlọrun Allah gba a, ko si ka a mọ awọn ayanfẹ. Mo padanu ọrẹ daadaa ati arabinrin mi. Sun un re o, ọrẹ mi, aya Adisa.’’

Epe buruku ni awọn mi-in n ṣẹ lu awọn to ṣeku pa obinrin naa.

Leave a Reply