Awọn ajinigbe ti tu eeyan marun-un ti wọn ji l’Ekiti silẹ

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti kede pe awọn ajinigbe ti yọnda awọn marun-un to wa lakata wọn silẹ.

Awọn eeyan ọhun ni wọn ji gbe lọsẹ to kọja yii ni opopona to lọ lati Ayedun-Ilasa-Ayebode Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, nipinlẹ Ekiti.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe oun o le sọ boya mọlebi awọn ti wọn ji ko naa sanwo ki wọn too gba iyọnda.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii lawọn ajinigbe ati awọn ṣọja doju ija kọra wọn lẹyin wakati diẹ ti wọn ji awọn kan gbe ni oju ọna naa, ki wọn too sa wọ inu igbo pẹlu awọn ti wọn ji gbe naa.

Yatọ si awọn marun-un ti wọn ji ko yii, marun-un ninu ero ọkọ naa ni wọn fara pa pẹlu bi wọn ṣe fi ara gbọta ibọn. Bakan naa ni awọn agbofinro tun mu awọn mẹfa lori ijinigbe naa.

Abutu ṣalaye pe igbo kan to wa ni Ikọle-Ekiti ni wọn ti tu awọn eeyan naa silẹ lẹyin ti awọn ọlọpaa ti ṣiṣẹ takuntakun pẹlu bi wọn ṣe wọnu igbo naa.

 

O ṣalaye pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ko awọn ajinigbe tọwọ tẹ naa lọ sile-ẹjọ, ki wọn le foju wina ofin.

Leave a Reply