Awọn ajinigbe ti yọnda iyawo olori awọn oṣiṣẹ gomina Ondo ti wọn ji gbe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akure

Iyawo olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina ipinlẹ Ondo ti wọn ji gbe lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ni wọn ti yọnda rẹ lẹyin bii ọjọ meji to ti wa ninu igbekun awọn ajinigbe naa.

Abilekọ Ale atawọn obinrin meji mi-in la gbọ pe wọn bọ sọwọ awọn ajinigbe ọhun lagbegbe Ọwẹna, laarin oju ọna marosẹ Ondo si Akurẹ, lasiko to n bọ lati ilu Eko, nibi to ti lọọ ra ọja.

Ko sohun tawọn eeyan tun gbọ nipa ọrọ awọn ti wọn ji gbe naa mọ titi ti okiki fi kan lọsan-an ọjọ Abameta, Satide, pe wọn ti ri obinrin ọhun gba pada lọwọ awọn to ji i gbe.

Iyalẹnu lọro ijinigbe ọhun si n jẹ fawọn eeyan nitori pe igba akọkọ ree tiru iṣẹlẹ bẹẹ yoo waye lagbegbe naa.

Leave a Reply