Awọn ajinigbe to ji agbẹ mẹrin n’Ikosun-Ekiti n beere aadọta miliọnu naira

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Awọn ajinigbe to ji awọn agbẹ mẹrin gbe ni Ikosun-Ekiti ti beere aadọta miliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ wọn.

Ẹnikan to sun mọ ọkan lara awọn mọlẹbi  awọn agbẹ naa sọ pe awọn ajinigbe naa fi ẹrọ ilewọ ọkan lara awọn eeyan naa pe awọn ni nnkan bii aago mẹrin irọle, ti wọn si beere fun aadọta miliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ awọn agbẹ yii.

Tẹ o ba gbagbe, ni kutukutu aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni awọn eeyan yii ti ko din ni mẹfa ji awọn agbẹ mẹrin yii ko ninu oko wọn to wa niluu Ikosun-Ekiti, nijọba ibilẹ Mọba, nipinlẹ Ekiti.

Gẹgẹ bi awọn agbẹ to wa lagbegbe naa ṣe sọ, wọn ni awọn agbẹ naa jẹ agbẹ to n gbin irẹsi. Nigba ti awọn eeyan naa n ṣiṣẹ ninu oko wọn ni awọn ajinigbe naa ya bo wọn, ti wọn si ji wọn gbe lọ.

Ọba ilu naa, Joseph Afolabi Adeoye, ṣalaye fawọn oniroyin niluu Ado-Ekiti pe awọn agbẹ mẹrin naa, Gbadamọsi Sarafa, Jimoh, Yinka Adeniran ati Ṣeun ni wọn ji gbe laaarọ kutukutu ọjọ Iṣẹgun.

Ọba alaye yii ṣalaye pe awọn ajinigbe naa ti wọn ko din ni meje ni wọn dihamọra pẹlu ibọn ati ohun ija oloro mi-in pẹlu alupupu, ti wọn si kọ lu awọn eeyan naa. Meji lara awọn agbẹ yii jẹ dẹrẹba to n wa ẹrọ katakata, nigba ti awọn meji yooku jẹ agbẹ to n ṣọ ẹyẹ ninu oko irẹsi.

Nigba ti ALAROYE kan si Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, ỌgbẸni Sunday Abutu, o sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn oun ko mọ nipa aadọta miliọnu naira ti wọn sọ pe awọn ajinigbe naa n beere fun.

O fi kun un peawọn ọlọpaa ati awọn ọdẹ ibilẹ ti wa ninu igbo ati aginju to wa lagbegbe naa lati gba awọn agbẹ naa jade ni ayọ ati alaafia.

 

 

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: