Awọn ajinigbe to ji Bukunmi atawọn meji mi-in n beere fun miliọnu meji naira l’Omu-Aran

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ilọrin ni ọdọmọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Bukunmi n gbe, ko too lọọ ba Alhaji kan ṣiṣẹ oko niluu Omu-Aran, nipinlẹ Kwara, tawọn ajinigbe fi ji oun ati eeyan meji miiran gbe lọ, ti wọn si n beere fun miliọnu meji naira owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi wọn.

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, lawọn ajinigbe naa ji Bukunmi ati awọn meji miiran gbe lasiko ti Alhaji ti wọn ba ṣiṣẹ oko fi mọto ran wọn niṣẹ pe ki wọn lọọ ra ajilẹ niluu Ilọrin.

Awọn ajinigbe ti wọn sọ pe wọn dihamọra pẹlu ohun ija oloro da wọn lọna, wọn ji awọn mẹtẹẹta gbe lọ, wọn si fi mọto wọn silẹ si eti igbo.

Ni bayii, awọn ajinigbe ọhun ti pe awọn mọlẹbi wọn, ti wọn si n beere fun miliọnu meji naira owo itusilẹ lọwọ wọn.

Leave a Reply