Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọkunrin agbẹ nla kan, Alaaji Jimọh Ọlọdan, ni wọn ni awọn ajinigbe kan wọnu oko rẹ ni Iyemero-Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, ti wọn si gbe e sa lọ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii.
Gẹgẹ bi oloye kan torukọ rẹ n jẹ Ajayi Ogungbemi ṣe ṣalaye f’ALAROYE, o ni aago mejila oru fẹẹ lọọ lu lawọn ajinigbe ti wọn fura si pe Fulani ni wọn ti wọn ko din ni mejidinlogun de tibọn-tibọn wọnu oko Alaaji Jimọh, bi wọn ṣe gbe e sori ọkada ti wọn gbe wa niyẹn, ti wọn si sa lọ.
Oloye yii sọ pe bi wọn ṣe n gbe Alaaji Ọlọdan lọ ni wọn n yinbọn soke, pẹlu ọkada ti ko din ni mẹwaa ti wọn ko wọ oko naa wa, wọn si kọju sọna kan to jade sipinlẹ Kwara.
Iro ibọn yii lo ji awọn ara abule ọhun silẹ, to si da jinni-jinni bo wọn. O ni awọn mi-in sa jade ninu ile ti wọn sun si, wọn fori legbo lati sa asala fun ẹmi wọn.
“Oloye Ogunyẹmi ni, ”Eleyi ki i ṣe igba akọkọ ti awọn ajinigbe yoo waa jiiyan pataki gbe ninu ilu Iyemero, eyi fi han pe awọn Fulani to n ṣiṣẹ oko lagbegbe wa lo n ṣiṣẹ naa.
“Awọn Fulani lo n da oko meji kan lagbegbe yii torukọ wọn n jẹ Eleguro ati Atu ru, ti wọn si n ba ire oko awọn agbẹ agbegbe naa jẹ.”
Baba oloye yii rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ekiti atawọn ikọ Amọtẹkun pe ki wọn ran awọn lọwọ nipa eto aabo to mẹhẹ yii.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu, loun ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ yii. O lẹnikẹni ko ti i fi to ileeṣe ọlọpaa Ekiti leti.