Awọn ajinigbe tun ya wọn ileewe kan ti wọn pe ni Islamiyya School, to wa ni Tegina, nijọba ibilẹ Rafi, nipinlẹ Niger, wọn si ko awọn akẹkọọ ọgọrun-un meji lọ.
Ni nnkan bii aago mẹrin aabọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii la gbọ pe wọn ya bo ileewe naa, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn. Ibọn yii ba ẹni kan, nigba ti ẹlomi-in to fara kaasa ibọn yii wa lọsibitu to ti n gbatọju nitori ibọn naa ba a gidigidi.
ALAROYE gbọ pe ileewe ti wọn ti n kọ awọn ọmọ ni keu ni ileewe naa, awọn obi kọọkan lo si maa n mu awọn ọmọ wọn wa sibẹ lati waa kẹkọọ.
Bo tilẹ jẹ pe Akọwe ijọba nipinlẹ Niger, Ahmed Matane, ni awọn ko ti i mọ iye awọn akẹkọọ ti wọn ko lọ, sibẹ, awọn olugbe agbegbe tiṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ sọ pe awọn akẹkọọ ti wọn ko to ọgọrun-un meji.
Yatọ si agbegbe Tegina tawọn agbebọ naa ti ṣọṣẹ, a gbọ pe wọn tun ṣoro ni awọn ijọba ibilẹ meji mi-in, eyi to mu ko nira fawọn agbofinro lati mọ eyi ti wọn fẹẹ koju ninu wọn.