Awọn ajinigbe tun ji ọba alaye gbe ni Kogi

 Ọrọ awọn agbebọn yii ti waa kọja sisọ bayii, bi awọn kan ṣe n bọ loko ẹru wọn ni wọn tu n ji awọn mi-in gbe. Ni nnkan bii aago marun-un aabọ aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, yii, ni wọn tun ji Adele ọba kan, Alaaji Shaibu Usman, Eje ti ilu Ankpa, nipinlẹ Kogi lọ. Mọṣalaaṣi ilu naa to wa ni Ankpa, ni ọba naa n lọ lati kirun ti wọn fi dena de e, ti wọn si gbe e lọ sibi ti ẹnikẹni ko ti i mọ di ba a ṣe n sọ yii.

 ALAROYE gbọ pe wọn ti dena de ọkunrin naa nitosi mọṣalaaṣi yii ko to debẹ, bi ọba alaye naa si ṣe n wọbẹ bayii ni wọn gbe e, ti ko si ti i sẹni to mọ ibi to wa, bẹẹ lawọn ajinigbe yii ko ti i kan si awọn mọlẹbi lati mọ ohun ti wọn n fẹ gan-an.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kogi, Ayuba Edeh, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, bẹẹ lo ni gbogbo ipa lawọn yoo ṣa lati ri ọba alaye yii gba pada lọwọ awọn ajinnigbe naa.

 

Leave a Reply